Smiley face

Ibere Orin Apala, Fuji ati itan igbe aye Bobby Benson to se idasile Highlife nile Nigeria 2

E ka apa kini NIBI
 
Bobby Benson
Ojo kokanla osu kerin odun 1922 [11 April 1922] ni won bi Bernard Olabinjo Benson ti gbogbo eniyan mo si "Bobby" Benson ni ilu Ikorodu to wa nipinle Eko.

Ni akoko to wa ni ile iwe, o je omo to ja fafa. Kosi si eto idaraya, amuludun kan ti won gbe kale ti Bobby Benson ko ni si nibe.

Ni akoko to wo ile eko sekondiri. O gbiyanju lati ko ise aso rinran. Igba to jade sekondiri lo bere si ni lo ko bi won se fese kan. Ni awon akoko naa lo n da bi ogbon lati di afeseku bi ojo.


Sugbon sa, irin-ajo re pada gbe wo ilu Biritiko lati lo darapo mo awon awako oju omi. Saaju asiko yii, Bobby Benson ti sawari ebun orin re. Lara ohun elo orin to si feran lati maa fi sere ni duuru, jita ati feere fifon.

Nigba to di lodun 1944, Bobby Benson pinnu lati fi ise wako oju omi re sile lati lo da egbe orin kale to pe ni Negro Ballet.

Aseyori Bobby Benson lekenka to fi je wi pe ko si ilu alawo funfun ti ko gbe pate orin laaarin odun 1944 si 1947. Laarin akoko yii naa lo pade aya, Cassandra, to je omo ilu Scotland.

Lodun 1947 Bobby Benson pinu lati pada siluu Nigeria ati aye re lati wa da egbe Amuludun tuntun sile eleyii to ni oruko Bobby Benson ati Cassandra ninu


Bobby Benson and Cassandra Theatrical Party.

Ni awon akoko yii, ti Bobby Benson ba n korin, aya Cassandra yoo si ma tadi rekereke niwaju agbo lati gbe orin oko laruge. Pupo ninu awon orin Bobby Benson nigba naa lo je jita ati fere fifon.

Odun 1950 tun je odun to lapere ninu itesiwaju orin Bobby Benson. Odun yii lo fe e gbe orin re loju, nipa ninu awon omo egbe orin mokanla. Odun yii naa ni won si gbe orin won olokiki, TAXI DRIVER, to mi gbogbo ilu Eko, Naijiria ati Afirika jigijigi.

Ki a wa ki n se orin Taxi Driver nikan ni Bobby Benson se, aimoye orin lo gbe jade eleyii ti gbogbo re si je itewogba.

Lara awon orin re to gbayi bi isana eleeta ni Gentleman Bobby", "Iyawo se wo lose mi", "Mafe", "Nylon Dress" ati "Niger Mambo.

Pupu awon olorin highlife ti irawo jade leyin Bobby Benson ni won ti fi igba kan je omoleyin Bobby Benson. Lara won ni Roy Chicago , Sir Victor Uwaifo, Bayo Martins, Zeal Onyia ati Victor Olaiya

Awon kan tun se alaye Bobby Benson gege bi ojulowo amuludun eleyii ti ipate ariya re a maa jo awon eniyan loju. Yato si wi pe Bobby Benson je olorin, a maa se awada bakan naa a ma pidan keekeeke lati fi da awon eniyan laraya.

Ni nnkan bi odun 1970, Bobby Bnson a maa seto lori telufisan NTA ni to ti n sawada lati pa awon eniyan lerin bakan naa a maa korin lori eto re naa.

Nipase iriri Bobby Benson, opinu lati se idasile il ijo bi ti awon ilu oke okun to ti maa n korin tele. Bobby Benson se idasile ile ijo ti won pe ni Caban Bamboo.

Ile ijo yii gbajumo, nitori ohun ni ile ijo akoko ti yoo wa ni akoko naa. Igba to wa ni won tun so ile ijo yii di ile itura eleyii ti won pe ni Hotel Bobby.

Aimoye iyawo ni Bobby Benson ni leyin aya re Casandra bakan naa ni awon omo re n lo bi mewaa.

Ojo kerinla osu karun un odun 1983 ni Bobby Benson dagbere faye niluu Eko. Ojo Satide ni ojo naa bosi, awon egbe onifaaji akoko si sedaro agba olorin highlife ti a mo si Bobby Benson.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment